10. Ati awọn orilẹ-ède iyokù ti Asnapperi, ọlọla ati ẹni-nla nì, kó rekọja wá, ti o si fi wọn do si ilu Samaria, ati awọn iyokù ti o wà ni ihahin odò, ati ẹlomiran.
11. Eyi ni atunkọ iwe na ti nwọn fi ranṣẹ si i, ani si Artasasta ọba: Iranṣẹ rẹ, awọn enia ihahin odò ati ẹlomiran.
12. Ki ọba ki o mọ̀ pe, awọn Ju ti o ti ọdọ rẹ wá si ọdọ wa, nwọn de Jerusalemu, nwọn nkọ́ ọlọtẹ ilu ati ilu buburu, nwọn si ti fi odi rẹ̀ lelẹ, nwọn si ti so ipilẹ rẹ̀ mọra pọ̀.
13. Ki ọba ki o mọ̀ nisisiyi pe, bi a ba kọ ilu yi, ti a si tun odi rẹ̀ gbe soke tan, nigbana ni nwọn kì o san owo ori, owo-bode, ati owo odè, ati bẹ̃ni nikẹhin yio si pa awọn ọba li ara.
14. Njẹ nisisiyi lati ãfin ọba wá li a sa ti mbọ́ wa, kò si yẹ fun wa lati ri àbuku ọba, nitorina li awa ṣe ranṣẹ lati wi fun ọba daju;
15. Ki a le wá inu iwe-iranti awọn baba rẹ: bẹ̃ni iwọ o ri ninu iwe-iranti, iwọ o si mọ̀ pe, ọlọtẹ ni ilu yi, ti o si pa awọn ọba ati igberiko li ara, ati pe, nwọn ti ṣọtẹ ninu ikanna lati atijọ wá, nitori eyi li a fi fọ ilu na.
16. Awa mu u da ọba li oju pe, bi a ba tun ilu yi kọ, ti a si pari odi rẹ̀ nipa ọ̀na yi, iwọ kì o ni ipin mọ ni ihahin odò.
17. Nigbana ni ọba fi èsi ranṣẹ si Rehumu, adele-ọba, ati si Ṣimṣai, akọwe, pẹlu awọn ẹgbẹ wọn iyokù ti ngbe Samaria, ati si awọn iyokù li oke odò: Alafia! ati kiki miran.
18. A kà iwe ti ẹnyin fi ranṣẹ si wa dajudaju niwaju mi.
19. Mo si paṣẹ, a si ti wá, a si ri pe, lati atijọ wá, ilu yi a ti ma ṣọ̀tẹ si awọn ọba, ati pe irukerudo ati ọ̀tẹ li a ti nṣe ninu rẹ̀.
20. Pẹlupẹlu awọn ọba alagbara li o ti wà lori Jerusalemu, awọn ti o jọba lori gbogbo ilu oke-odò; owo ori, owo odè, ati owo bodè li a ti nsan fun wọn.
21. Ki ẹnyin ki o paṣẹ nisisiyi lati mu awọn ọkunrin wọnyi ṣiwọ, ki a má si kọ ilu na mọ, titi aṣẹ yio fi jade lati ọdọ mi wá.
22. Ẹ kiyesi ara nyin, ki ẹnyin ki o má jafara lati ṣe eyi: ẽṣe ti ìbajẹ yio fi ma dàgba si ipalara awọn ọba?
23. Njẹ nigbati a ka atunkọ iwe Artasasta ọba niwaju Rehumu, ati Ṣimṣai akọwe, ati awọn ẹgbẹ wọn, nwọn gòke lọ kankán si Jerusalemu, si ọdọ awọn Ju, nwọn si fi ipá pẹlu agbara mu wọn ṣiwọ.
24. Nigbana ni iṣẹ ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu, duro. Bẹ̃li o duro titi di ọdun keji Dariusi, ọba Persia.