2. Awọn ti o ba Serubbabeli wá, Jeṣua, Nehemiah, Seraiah, Reelaiah, Mordekai, Bilṣani, Mispari, Bigfai, Rehumu, Baana. Iye awọn ọkunrin ninu awọn enia Israeli:
3. Awọn ọmọ Paroṣi, ẹgbọkanla o din mejidilọgbọn.
4. Awọn ọmọ Ṣefatiah, irinwo o din mejidilọgbọn.
5. Awọn ọmọ Ara, ẹgbẹrin o din mẹ̃dọgbọn.
6. Awọn ọmọ Pahati-Moabu ninu awọn ọmọ Jeṣua, ati Joabu, ẹgbẹrinla o le mejila.
7. Awọn ọmọ Elamu, adọtalelẹgbẹfa o le mẹrin.
8. Awọn ọmọ Sattu, ọtadilẹgbẹ̀run, o le marun.
9. Awọn ọmọ Sakkai, ojidilẹgbẹrin.
10. Awọn ọmọ Bani, ojilelẹgbẹta, o le meji.
11. Awọn ọmọ Bebai, ẹgbẹta o le mẹtalelogun.
12. Awọn ọmọ Asgadi, ẹgbẹfa, o le mejilelogun.
13. Awọn ọmọ Adonikami ọtalelẹgbẹta o le mẹfa.