4. Dide! nitori ọran tirẹ li eyi: awa pãpã yio wà pẹlu rẹ, mu ọkàn le ki o si ṣe e.
5. Esra si dide, o si mu awọn olori ninu awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Israeli bura pe, awọn o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Nwọn si bura.
6. Esra si dide kuro niwaju ile Ọlọrun, o si wọ̀ yara Johanani ọmọ Eliaṣibu lọ: nigbati o si lọ si ibẹ, on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi: nitoripe o nṣọ̀fọ nitori irekọja awọn ti a kó lọ.
7. Nwọn si kede ja gbogbo Juda ati Jerusalemu fun gbogbo awọn ọmọ igbèkun, ki nwọn ki o kó ara wọn jọ pọ̀ si Jerusalemu;
8. Ati pe ẹnikẹni ti kò ba wá niwọ̀n ijọ mẹta, gẹgẹ bi ìmọ awọn olori ati awọn agba, gbogbo ini rẹ̀ li a o jẹ, on tikararẹ̀ li a o si yà kuro ninu ijọ awọn enia ti a ti ko lọ.
9. Nitori eyi ni gbogbo awọn enia Juda ati Benjamini ko ara wọn jọ pọ̀ ni ọjọ mẹta si Jerusalemu, li oṣu kẹsan, li ogun ọjọ oṣu; gbogbo awọn enia si joko ni ita ile Ọlọrun ni iwarìri nitori ọ̀ran yi, ati nitori òjo-pupọ.