Esr 10:17-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Nwọn si ba gbogbo awọn ọkunrin ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe ṣe aṣepari, li ọjọ ekini oṣu ekini.

18. Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa, a ri awọn ti o mu ajeji obinrin ba wọn gbe: ninu awọn ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati awọn arakunrin rẹ̀; Maaseiah, ati Elieseri, ati Jaribi ati Gedaliah.

19. Nwọn si fi ọwọ wọn fun mi pe: awọn o kọ̀ awọn obinrin wọn silẹ; nwọn si fi àgbo kan rubọ ẹ̀ṣẹ nitori ẹbi wọn.

20. Ati ninu awọn ọmọ Immeri; Hanani ati Sebadiah.

21. Ati ninu awọn ọmọ Harimu; Maaseiah, ati Elija, ati Ṣemaiah, ati Jehieli, ati Ussiah.

22. Ati ninu awọn ọmọ Paṣuri; Elioenai, Maaseiah, Iṣmaeli, Nataneeli Josabadi, ati Eleasa.

Esr 10