Esek 7:23-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Rọ ẹ̀wọn kan; nitori ilẹ na kún fun ẹ̀ṣẹ ẹjẹ, ilu-nla na si kún fun iwa ipa.

24. Nitorina li emi o mu awọn keferi ti o burujulọ, nwọn o si jogun ile wọn: emi o si mu ọṣọ-nla awọn alagbara tán pẹlu, ibi mimọ́ wọn li a o si bajẹ.

25. Iparun mbọ̀ wá, nwọn o si wá alafia, kì yio si si.

26. Tulasì yio gori tulasi, irọkẹ̀kẹ yio si gori irọkẹ̀kẹ; nigbana ni nwọn o bere lọdọ woli; ṣugbọn ofin yio ṣegbé kuro lọdọ alufa, ati imọ̀ kuro lọdọ awọn agbà.

27. Ọba yio ṣọ̀fọ, a o si fi idahoro wọ̀ ọmọ-alade, ọwọ́ awọn enia ilẹ na li a o wahala, emi o ṣe si wọn gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi ẹjọ wọn ti ri li emi o dá a fun wọn: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esek 7