Esek 7:12-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Akoko na de, ọjọ na sunmọ itosi: ki olùra máṣe yọ̀, bẹ̃ni ki olùta máṣe gbãwẹ: nitori ibinu de ba gbogbo wọn.

13. Nitori olùta kì yio pada si eyi ti a tà, bi wọn tilẹ wà lãye: nitori iran na kàn gbogbo enia ibẹ̀, ti kì yio pada; bẹ̃ni kò si ẹniti yio mu ara rẹ̀ le ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀.

14. Nwọn ti fọn ipè, lati jẹ ki gbogbo wọn mura; ṣugbọn kò si ẹnikan ti o lọ si ogun: nitori ibinu mi wà lori gbogbo wọn.

15. Idà mbẹ lode, ajakálẹ àrun ati iyàn si mbẹ ninu: ẹniti o wà li oko yio kú nipa idà; ẹniti o wà ninu ilu, iyàn ati ajakálẹ àrun ni yio si jẹ ẹ run.

16. Ṣugbọn awọn ti o bọ́ ninu wọn yio salà, nwọn o si wà lori oke bi adabà afonifoji, gbogbo nwọn o ma gbãwẹ, olukuluku nitori aiṣedede rẹ̀.

17. Gbogbo ọwọ́ ni yio rọ, gbogbo ẽkun ni yio si di ailera bi omi.

18. Aṣọ ọ̀fọ ni nwọn o fi gbajá pẹlu; ìbẹru ikú yio si bò wọn mọlẹ; itiju yio si wà loju gbogbo wọn, ẽpá yio si wà li ori gbogbo wọn.

Esek 7