1. IWỌ, ọmọ enia, mu ọbẹ mimú, mu abẹ onigbajamọ̀, ki o si mu u kọja li ori rẹ, ati ni irùngbọn rẹ: si mu oṣuwọ̀n lati wọ̀n, ki o si pin irun na.
2. Iwọ o si fi iná sun idamẹta li ãrin ilu, nigbati ọjọ didotì ba pé: iwọ o si mu idamẹta, ki o si fi ọbẹ bù u kakiri: idamẹta ni iwọ o si tuka sinu ẹfũfù, emi o si yọ idà tẹle wọn.
3. Iwọ o si mu iye diẹ nibẹ, iwọ o si dì wọn si eti aṣọ rẹ.
4. Si tun mu ninu wọn, ki o si sọ wọn si ãrin iná, ki o si sun wọn ninu iná; lati inu rẹ̀ wá ni iná o ti jade wá si gbogbo ile Israeli.