20. Gbogbo ọrẹ na yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, nipa ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun: ẹ o si ta ọrẹ mimọ́ na, igun mẹrẹrin lọgbọ̃gba pẹlu ini ilu-nla na.
21. Ati iyokù yio jẹ ti olori, ni ihà kan, ati nihà keji ti ọrẹ mimọ́ na, ati ti ini ibi nla na, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ọrẹ ti àgbegbe ila-õrun, ati nihà iwọ-õrun ni ikọjusi ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun, nihà àgbegbe iwọ-õrun, ni ikọjusi awọn ipin ti olori: yio si jẹ ọrẹ mimọ́ na; ibi mimọ́ ile na, yio si wà lãrin rẹ̀.
22. Ati lati ini awọn Lefi, ati lati ini ti ilu-nla na, lãrin eyiti iṣe ti olori, lãrin àgbegbe Juda, ati lãrin àgbegbe Benjamini, yio jẹ ti olori.
23. Ati fun awọn ẹ̀ya iyokù, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Benjamini ipin kan.
24. Ati ni àgbegbe Benjamini, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Simeoni ipin kan.
25. Ati ni àgbegbe Simeoni, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Issakari ipin kan.
26. Ati ni àgbegbe Issakari, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Sebuloni ipin kan.
27. Ati ni àgbegbe Sebuloni, lati ihà ila-õrun de ihà iwọ-õrun, Gadi ipin kan.