19. Awọn ti mba nsìn ilu-nla na yio si ma sìn i, lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli.
20. Gbogbo ọrẹ na yio jẹ ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, nipa ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun: ẹ o si ta ọrẹ mimọ́ na, igun mẹrẹrin lọgbọ̃gba pẹlu ini ilu-nla na.
21. Ati iyokù yio jẹ ti olori, ni ihà kan, ati nihà keji ti ọrẹ mimọ́ na, ati ti ini ibi nla na, ni ikọjusi ẹgbã-mejila o le ẹgbẹrun, ọrẹ ti àgbegbe ila-õrun, ati nihà iwọ-õrun ni ikọjusi ẹgbã-mejila, o le ẹgbẹrun, nihà àgbegbe iwọ-õrun, ni ikọjusi awọn ipin ti olori: yio si jẹ ọrẹ mimọ́ na; ibi mimọ́ ile na, yio si wà lãrin rẹ̀.