1. O si mu mi padà wá si ibi ilẹkùn ile na; si kiyesi i, omi ntù jade lati abẹ iloro ile na nihà ila-õrun: nitori iwaju ile na wà ni ila-õrun, omi si nwalẹ lati abẹ apa ọtun ile na, ni gusu pẹpẹ.
2. O si mu mi jade ni ọ̀na ẹnu-ọ̀na ihà ariwa, o si mu mi yi wá ọ̀na ode si ẹnu-ọ̀na ode ni ọ̀na ti o kọjusi ila-õrun; si kiyesi i, omi ṣàn jade lati ihà ọtun.
3. Nigbati ọkunrin na jade sihà ila-õrun, pẹlu okùn kan lọwọ rẹ̀, o si wọ̀n ẹgbẹrun igbọnwọ, o si mu mi là omi na ja; omi na si de kókosẹ̀.