10. Ati olori ti o wà lãrin wọn, nigbati nwọn ba wọle, yio wọle; nigbati nwọn ba si jade, yio jade.
11. Ati ninu awọn asè ati ninu awọn ajọ, ọrẹ-ẹbọ jijẹ yio jẹ efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ-malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.
12. Nigbati olori na yio ba si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun atinuwá, tabi ọrẹ-ẹbọ idupẹ atinuwá fun Oluwa, ẹnikan yio si ṣi ilẹkun ti o kọjusi ila-õrun fun u, yio si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ idupẹ rẹ̀, bi o ti ṣe li ọjọ-isimi: yio si jade; ati lẹhin ijadelọ rẹ̀ ẹnikan yio tì ilẹkun.
13. Li ojojumọ ni iwọ o pèse ọdọ agutan kan alailabawọn ọlọdun kan fun ọrẹ-ẹbọ sisun fun Oluwa: iwọ o ma pèse rẹ̀ lorowurọ̀.
14. Iwọ o si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun u lorowurọ̀, idamẹfa efa, ati idamẹfa hini ororo kan, lati fi pò iyẹfun daradara na; ọrẹ-ẹbọ jijẹ nigbagbogbo nipa aṣẹ lailai fun Oluwa.
15. Bayi ni nwọn o pèse ọdọ-agutan na, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ na, ati ororo na, lojojumọ fun ọrẹ-ẹbọ sisun nigbagbogbo.
16. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi olori na ba fi ẹbùn fun ẹnikẹni ninu awọn ọmọ rẹ̀, ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀; yio jẹ ini wọn nipa ijogun.