9. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ki o to fun nyin, ẹnyin olori Israeli: ẹ mu ìwa ipa irẹ́jẹ kuro, ki ẹ si mu idajọ ati ododo ṣẹ, mu ilọ́nilọwọgbà nyin kuro lọdọ awọn enia mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.
10. Ki ẹnyin ki o ni ìwọn títọ, ati efà títọ, ati bati títọ.
11. Efa ati bati yio jẹ ìwọn kanna, ki bati ba le gbà ìdamẹwa homeri, ati efa idamẹwa homeri: iwọ̀n rẹ̀ yio jẹ gẹgẹ bi ti homeri.
12. Ṣekeli yio si jẹ́ ogún gera: ogún ṣekeli, ṣekeli mẹdọgbọ̀n, ṣekeli mẹdogun, ni manẹ nyin yio jẹ.
13. Eyi ni ọrẹ ti ẹ o rú; idamẹfa efa homeri alikama kan, ẹ o si mu idamẹfa efa homeri barle kan wá.
14. Niti aṣẹ oróro, bati oróro, idamẹwa bati kan, lati inu kori wá, ti o jẹ homeri onibati mẹwa; nitori bati mẹwa ni homeri kan:
15. Ati ọdọ-agutan kan lati inu agbo, lati inu igba, lati inu pápa tutù Israeli; fun ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati fun ọrẹ ẹbọ sisun, fun ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati fi ṣe ètutu fun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.