Esek 45:11-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Efa ati bati yio jẹ ìwọn kanna, ki bati ba le gbà ìdamẹwa homeri, ati efa idamẹwa homeri: iwọ̀n rẹ̀ yio jẹ gẹgẹ bi ti homeri.

12. Ṣekeli yio si jẹ́ ogún gera: ogún ṣekeli, ṣekeli mẹdọgbọ̀n, ṣekeli mẹdogun, ni manẹ nyin yio jẹ.

13. Eyi ni ọrẹ ti ẹ o rú; idamẹfa efa homeri alikama kan, ẹ o si mu idamẹfa efa homeri barle kan wá.

14. Niti aṣẹ oróro, bati oróro, idamẹwa bati kan, lati inu kori wá, ti o jẹ homeri onibati mẹwa; nitori bati mẹwa ni homeri kan:

15. Ati ọdọ-agutan kan lati inu agbo, lati inu igba, lati inu pápa tutù Israeli; fun ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati fun ọrẹ ẹbọ sisun, fun ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati fi ṣe ètutu fun wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.

16. Gbogbo enia ilẹ na ni yio mu ẹbọ yi wá fun olori ni Israeli.

17. Ti ọmọ-alade yio jẹ́ ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ mimu, ninu asè gbogbo, ati ni oṣù titun, ati ni awọn ọjọ isimi, ni gbogbo ajọ ile Israeli: on o pèse ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ idupẹ, lati ṣe etùtu fun ile Israeli.

18. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; li oṣù ekini, li ọjọ ekini oṣù, iwọ o mu ẹgbọ̀rọ akọ malu alailabawọn, iwọ o si fi sọ ibi mimọ́ di mimọ́:

19. Alufa yio si mu ninu ẹjẹ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, yio si fi si opó ile, ati si igun mẹrẹrin ijoko pẹpẹ, ati si opó ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu ile.

20. Bayi ni iwọ o si ṣe li ọjọ keje oṣù fun olukuluku ẹniti o ṣina, ati fun òpe: ẹ o si ṣe etùtu ilẹ na.

21. Li oṣù ekini, li ọjọ ẹkẹrinla oṣù, ẹnyin o ni irekọja, asè ọjọ meje: akara aiwú ni jijẹ.

22. Ati li ọjọ na ni ọmọ-alade yio pèse ẹgbọ̀rọ akọ malu fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ara rẹ̀ ati fun gbogbo enia ilẹ na.

Esek 45