1. PẸLUPẸLU nigbati ẹnyin ba fi ibo pín ilẹ li ogún, ẹ o gbé ọrẹ wá fun Oluwa, eyiti o mọ́ lati ilẹ na wá: gigùn na yio jẹ ẹgbã le ẹgbẹrun ije ni gigùn, ati ẹgbãrun ni ibú. Eyi yio jẹ́ mimọ́ ni gbogbo àgbegbe rẹ̀ yika.
2. Lati inu eyi, ẹ̃dẹgbẹta yio jẹ ti ibi-mimọ́ ni gigùn, pẹlu ẹ̃dẹgbẹta ni ibú, ni igun mẹrẹrin yika; ati adọta igbọnwọ fun igbangba rẹ̀ yika.
3. Ati ninu ìwọn yi ni iwọ o wọ̀n ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, ati ẹgbarun ni ibú; ati ninu rẹ̀ ni ibi-mimọ́ yio wà, ibi-mimọ́ julọ.
4. Eyi ti o mọ́ ninu ilẹ na yio jẹ ti awọn alufa, awọn iranṣẹ ibi-mimọ́, ti yio sunmọ lati ṣe iránṣẹ fun Oluwa: yio si jẹ àye fun ile wọn, ati ibi-mimọ́ fun ibi-mimọ́.
5. Ati ẹgbã mejila le ẹgbẹrun ni gigun, ati ti ẹgbãrun ni ibú, ni awọn Lefi, pẹlu awọn iranṣẹ ile na, ni ogún yará, fun ara wọn, ni ini.
6. Ati ini ilu na li ẹnyin o yàn ẹgbarun ni ibú, ati ẹgba mejila le ẹgbẹrun ni gigùn, lẹba ọrẹ ipín mimọ́ na: yio jẹ ti gbogbo ile Israeli.
7. Ati ipín kan yio jẹ ti olori nihà kan ati niha keji ọrẹ ipin mimọ́, ati ti ini ilu, ti o kọju si ọrẹ ipín mimọ́, ti o si kọju si iní ti ilu, lati iha iwọ-õrun si iwọ-õrun, ati lati ihà ila-õrun si ila-õrun: gigùn rẹ̀ yio gbe ọkan ninu awọn ipín, lati eti iwọ-õrun de eti ila-õrun.
8. Ni ilẹ na ni iní rẹ̀ yio wà ni Israeli: awọn olori mi kì yio si ni awọn enia mi lara mọ́; ati ilẹ iyokù ni nwọn o fi fun ile Israeli gẹgẹ bi ẹyà wọn.
9. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ki o to fun nyin, ẹnyin olori Israeli: ẹ mu ìwa ipa irẹ́jẹ kuro, ki ẹ si mu idajọ ati ododo ṣẹ, mu ilọ́nilọwọgbà nyin kuro lọdọ awọn enia mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.