1. O si mu mi pada lọna ẹnu-ọ̀na ibi mimọ́ ti ode ti o kọju si ila-õrun; o si tì.
2. Oluwa si wi fun mi pe; Ẹnu-ọ̀na yi yio wà ni titì, a kì yio ṣi i, ẹnikan kì yio si gbà a wọ inu rẹ̀; nitori Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti gbà a wọ inu rẹ̀, yio si wà ni titì.
3. Fun ọmọ-alade ni; ọmọ-alade, on ni yio joko ninu rẹ̀ lati jẹ akara niwaju Oluwa; yio wọ̀ ọ lati ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na na, yio si jade lati ọ̀na rẹ̀ na lọ.
4. O si mu mi wá ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa siwaju ile na; mo si wò, si kiyesi i, ogo Oluwa kun ile Oluwa: mo si doju mi bolẹ.
5. Oluwa si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi iyè rẹ si i, si fi oju rẹ wò, si fi eti rẹ gbọ́ ohun gbogbo ti emi ti sọ fun ọ niti gbogbo aṣẹ ile Oluwa, ati ti gbogbo ofin rẹ̀; si fi iyè rẹ si iwọ̀nu ile nì, pẹlu gbogbo ijadelọ ibi-mimọ́ na.