Esek 43:21-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Iwọ o si mu ẹgbọrọ malu ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, on o si sun u ni ibiti a yàn ni ile na lode ibi-mimọ́.

22. Ati ni ọjọ keji iwọ o fi ọmọ ewurẹ alailabawọn rubọ ọrẹ ẹ̀ṣẹ; nwọn o si sọ pẹpẹ na di mimọ́, bi nwọn iti ifi ẹgbọrọ malu sọ ọ di mimọ́.

23. Nigbati iwọ ba ti sọ ọ di mimọ tan, iwọ o fi ẹgbọrọ malu alailabawọn rubọ, ati àgbo alailabawọn lati inu agbo wá.

24. Iwọ o si fi wọn rubọ niwaju Oluwa, awọn alufa yio si dà iyọ̀ si wọn, nwọn o si fi wọn rú ọrẹ ẹbọ sisun si Oluwa.

25. Ọjọ meje ni iwọ o fi pèse obukọ fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ lojojumọ: nwọn o si pèse ẹgbọrọ malu pẹlu ati àgbo lati inu agbo wá, ti nwọn ṣe ailabawọn.

26. Ọjọ meje ni nwọn o fi wẹ̀ pẹpẹ, nwọn o si sọ ọ di mimọ́: nwọn o si yà ara wọn sọtọ̀.

Esek 43