18. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni aṣẹ pẹpẹ na li ọjọ ti nwọn o ṣe e, lati rú ọrẹ ẹbọ sisun lori rẹ̀, ati lati wọ́n ẹ̀jẹ sori rẹ̀.
19. Iwọ o si fi ẹgbọrọ malu, fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, fun awọn alufa, awọn Lefi, ti iṣe iru-ọmọ Sadoku, ti nsunmọ mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.
20. Iwọ o si mu ninu ẹjẹ rẹ̀, iwọ o si fi si iwo mẹrẹrin rẹ̀, ati si igun mẹrẹrin ijoko na, ati si eti rẹ̀ yika: iwọ o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọ́, iwọ o si ṣe etùtu rẹ̀.
21. Iwọ o si mu ẹgbọrọ malu ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, on o si sun u ni ibiti a yàn ni ile na lode ibi-mimọ́.
22. Ati ni ọjọ keji iwọ o fi ọmọ ewurẹ alailabawọn rubọ ọrẹ ẹ̀ṣẹ; nwọn o si sọ pẹpẹ na di mimọ́, bi nwọn iti ifi ẹgbọrọ malu sọ ọ di mimọ́.