Esek 42:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Bẹ̃ gẹgẹ ni yará ti on ti ilẹkùn wọn li ọ̀na gusu, ilẹkùn kan wà lori ọ̀na, li ọ̀na gbọran niwaju ogiri li ọ̀na ila-õrun bi a ti nwọ̀ inu wọn.

13. O si wi fun mi pe, Awọn yará ariwa ati awọn yará gusu, ti o wà niwaju ibiti a yà sọtọ̀, awọn ni yará mimọ́, nibiti awọn alufa ti nsunmọ Oluwa yio ma jẹ ohun mimọ́ julọ: nibẹ̀ ni nwọn o ma gbe ohun mimọ́ julọ kà, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; nitori ibẹ̀ jẹ mimọ́.

14. Nigbati awọn alufa ba wọ̀ ibẹ̀, nwọn kì yio si kuro ni ibi mimọ́ si agbala ode, ṣugbọn nibẹ nibiti nwọn gbe nṣiṣẹ ni nwọn o fi ẹwù wọn si; nitori nwọn jẹ mimọ́; nwọn o si wọ̀ ẹwù miran, nwọn o si sunmọ nkan wọnni ti o jẹ́ ti enia.

15. Nigbati o si ti wọ̀n ile ti inu tan, o mu mi wá sihà ilẹkùn ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si wọ̀n yika.

16. O fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ila-õrun, ẹ̃dẹgbẹta ije, nipa ije iwọ̀nlẹ yika.

17. O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ariwa, ẹ̃dẹgbẹta ije yika.

Esek 42