1. O si mu mi wá si tempili, o si wọ̀n awọn atẹrigbà, igbọnwọ mẹfa ni gbigborò li apakan, igbọnwọ mẹfa ni gbigborò li apakeji, ibú agọ na.
2. Ati ibú ilẹkùn na jẹ igbọnwọ mẹwa; ihà ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ marun li apakan, ati igbọnwọ marun li apakeji; o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogoji igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ.
3. O si wá si inu rẹ̀, o si wọ̀n atẹrigbà ilẹkùn na, igbọnwọ meji; ati ilẹkùn na, igbọnwọ mẹfa; ibú ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ meje.
4. Bẹ̃ li o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogún igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ, niwaju tempili: o si wi fun mi pe, Eyi ni ibi mimọ́ julọ.
5. O si wọ̀n ogiri ile na, igbọnwọ mẹfa; ati ibú yàrá-ihà gbogbo igbọnwọ mẹrin, yi ile na ka nihà gbogbo.