1. LI ọdun kẹ̃dọgbọn oko-ẹrú wa, ni ibẹ̀rẹ ọdun na, li ọjọ ikẹwa oṣù, li ọdun ikẹrinla lẹhin igbati ilu fọ́, li ọjọ na gan, ọwọ́ Oluwa wà lara mi, o si mu mi wá sibẹ na.
2. Ninu iran Ọlọrun li o mu mi wá si ilẹ Israeli, o si gbe mi ka oke giga kan, lori eyiti kikọ ilu wà ni iha gusu.
3. O si mu mi wá sibẹ, si kiyesi i, ọkunrin kan mbẹ, ẹniti irí rẹ̀ dabi irí bàba, pẹlu okùn ọ̀gbọ li ọwọ́ rẹ̀, ati ije iwọ̀nlẹ; on si duro ni ẹnu-ọ̀na.
4. Ọkunrin na si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi oju rẹ wò, ki o si fi eti rẹ gbọ́, ki o si gbe ọkàn rẹ le ohun gbogbo ti emi o fi han ọ; nitori ka ba le fi wọn han ọ li a ṣe mu ọ wá ihinyi: sọ ohun gbogbo ti o ri fun ile Israeli.