6. Nigbati iwọ ba si pari wọn, tun fi ẹgbẹ́ rẹ ọtún dubulẹ, iwọ o si ru ẹ̀ṣẹ ile Juda li ogoji ọjọ: mo ti yàn ọjọ kan fun ọdun kan fun ọ.
7. Nitorina iwọ o kọju si didótì Jerusalemu, iwọ ki yio si bo apá rẹ, iwọ o si sọ asọtẹlẹ si i.
8. Si kiyesi i, emi o fi idè le ara rẹ, iwọ ki yio si yipada lati ihà kan de ekeji, titi iwọ o fi pari gbogbo ọjọ didotì rẹ.
9. Si mu alikama, ati ọka bàba, erẽ ati lentile ati milleti, ati ẹwẹ, fi wọn sinu ikoko kan, ki o si fi wọn ṣe akara, gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ li ẹgbẹ́ rẹ, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ ni iwọ o jẹ ninu rẹ̀.
10. Iwọ o si jẹ onjẹ rẹ nipa ìwọn, ogún ìwọn ṣekeli li ọjọ kan, lati akoko de akoko ni iwọ o jẹ ẹ.
11. Iwọ o si mu omi nipa ìwọn, idamẹfa oṣuwọ̀n hini kan: lati akoko de akoko ni iwọ o mu u.
12. Iwọ o si jẹ ẹ bi akara ọka bàba, iwọ o si fi igbẹ́ enia din i, li oju wọn.
13. Oluwa si wipe, Bayi li awọn ọmọ Israeli yio jẹ akara aimọ́ wọn larin awọn keferi, nibiti emi o le wọn lọ.