Esek 39:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NITORINA, iwọ ọmọ enia, sọtẹlẹ si Gogu, si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi dojukọ́ ọ, iwọ Gogu, olori ọmọ-alade Meṣeki ati Tubali:

2. Emi o si dá ọ padà, emi o si dári rẹ, emi o si mu ọ goke wá lati ihà ariwa, emi o si mu ọ wá sori oke giga Israeli:

3. Emi o si lù ọrun rẹ kurò li ọwọ́ osì rẹ, emi o si mu ọfà rẹ bọ kuro lọwọ ọtun rẹ.

4. Iwọ o ṣubu lori òke giga Israeli, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ: emi o fi ọ fun ẹiyẹ ọdẹ onirũru iyẹ, ati ẹranko igbẹ lati pa jẹ.

5. Iwọ o ṣubu ni gbangba oko: nitori emi li o sọ ọ, ni Oluwa Ọlọrun wi.

6. Emi o si rán iná si Magogu, ati sãrin awọn ti ngbe erekuṣu laibẹ̀ru; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

7. Emi o si sọ orukọ mimọ́ mi di mimọ̀ lãrin enia mi Israeli; emi kì yio si jẹ ki nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ mọ: awọn orilẹ-ède yio si mọ̀ pe emi li Oluwa, Ẹni-Mimọ́ ni Israeli.

8. Kiye si i, o ti de, a si ti ṣe e; ni Oluwa Ọlọrun wi, eyi ni ọjọ ti emi ti sọ.

9. Awọn ti o si ngbe ilu Israeli yio jade lọ, nwọn o si fi ohun ihamọra wọnni jona ati asa ati apata, ọrun ati ọfà, kùmọ ati ọ̀kọ; nwọn o si fi iná sun wọn li ọdun meje:

10. Nwọn kì yio lọ rù igi lati inu oko wá, bẹ̃ni nwọn kì yio ke igi lulẹ lati inu igbẹ́ wá; nitori ohun ihamọra ni nwọn ti fi daná; nwọn o si ko awọn ti o ko wọn, nwọn o si dọdẹ awọn ti o dọdẹ wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.

Esek 39