Esek 37:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ỌWỌ́ Oluwa wà li ara mi, o si mu mi jade ninu ẹmi Oluwa, o si gbe mi kalẹ li ãrin afonifojì ti o kún fun egungun,

2. O si mu mi rìn yi wọn ka: si wò o, ọ̀pọlọpọ ni mbẹ ni gbangba afonifojì; si kiyesi i, nwọn gbẹ pupọpupọ.

3. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, egungun wọnyi le yè? Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ li o le mọ̀.

4. O tun wi fun mi pe, Sọtẹlẹ sori egungun wọnyi, si wi fun wọn pe, Ẹnyin egungun gbigbẹ, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa.

5. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun egungun wọnyi; Kiyesi i, emi o mu ki ẽmi wọ̀ inu nyin, ẹnyin o si yè:

6. Emi o si fi iṣan sara nyin, emi o si mu ẹran wá sara nyin, emi o si fi àwọ bò nyin, emi o si fi ẽmi sinu nyin, ẹnyin o si yè; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esek 37