1. ATI iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oke Israeli, si wipe, Ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:
2. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nitori ti ọta ti wi si nyin pe, Aha, ani ibi giga igbãni jẹ tiwa ni ini:
3. Nitorina sọtẹlẹ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Nitõtọ nitori nwọn ti sọ ọ di ahoro, ti nwọn si gbe ọ mì niha gbogbo, ki ẹnyin ba le jẹ ini fun awọn keferi iyokù, ti a mu nyin si ẹnu, ti ẹnyin si jasi ẹ̀gan awọn enia: