Esek 35:7-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Bayi li emi o sọ oke Seiri di ahoro patapata, emi o si ké ẹniti nkọja lọ ati ẹniti npadà bọ̀ kuro ninu rẹ̀.

8. Emi o si fi awọn okú rẹ̀ kún awọn oke rẹ̀; ni oke kékèké rẹ, ati ni afonifoji rẹ, ati ni gbogbo odò rẹ li awọn ti a fi idà pa yio ṣubu si.

9. Emi o sọ ọ di ahoro lailai, awọn ilu rẹ kì yio si padà bọ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.

10. Nitoriti iwọ ti wipe, Awọn orilẹ-ède mejeji yi, ati awọn ilẹ mejeji yi yio jẹ́ ti emi, awa o si ni i; nigbati o ṣepe Oluwa wà nibẹ:

11. Nitorina, bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi emi o tilẹ ṣe gẹgẹ bi ibinu rẹ, ati gẹgẹ bi ilara rẹ ti iwọ ti lò lati inu irira rẹ si wọn; emi o si sọ ara mi di mimọ̀ lãrin wọn, nigbati emi ba ti da ọ li ẹjọ.

12. Iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa, ati pe emi ti gbọ́ ọ̀rọ buburu rẹ, ti iwọ ti sọ si oke Israeli, wipe, A sọ wọn di ahoro, a fi wọn fun wa lati run.

13. Bayi li ẹnyin ti fi ẹnu nyin buná si mi, ẹ si ti sọ ọ̀rọ nyin di pupọ si mi: emi ti gbọ́.

14. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi pe, Nigbati gbogbo aiye nyọ̀, emi o sọ ọ di ahoro.

15. Gẹgẹ bi iwọ ti yọ̀ si ini ile Israeli, nitori ti o di ahoro, bẹ̃li emi o ṣe si ọ; iwọ o di ahoro, iwọ oke Seiri ati gbogbo Idumea, ani gbogbo rẹ̀: nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Esek 35