Esek 34:29-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

29. Emi o si gbe igi okiki kan soke fun wọn, ebi kì yio si run wọn ni ilẹ na mọ, bẹ̃ni nwọn kì yio rù itiju awọn keferi mọ.

30. Bayi ni nwọn o mọ̀ pe emi Oluwa Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn, ati awọn, ile Israeli, jẹ enia mi, li Oluwa Ọlọrun wi.

31. Ati ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, ọwọ́-ẹran pápa oko mi ni enia, emi si li Ọlọrun nyin, li Oluwa Ọlọrun wi.

Esek 34