Esek 34:16-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Emi o wá eyiti o sọnu lọ, emi o si mu eyiti a lé lọ pada bọ̀, emi o si dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, emi o mu eyiti o ṣaisan li ara le; ṣugbọn emi o run eyiti o sanra ati eyiti o lagbara; emi o fi idajọ bọ́ wọn.

17. Bi o ṣe ti nyin, Ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i emi o ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran, lãrin àgbo ati obukọ.

18. Ohun kekere ni li oju nyin ti ẹ ti jẹ oko daradara, ṣugbọn ẹnyin si fi ẹsẹ tẹ̀ oko iyokù mọlẹ, ati ti ẹ ti mu ninu omi jijìn, ṣugbọn ẹ si fi ẹsẹ ba eyi ti o kù jẹ?

19. Bi o ṣe ti ọwọ́-ẹran mi ni, nwọn jẹ eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin tẹ̀ mọlẹ; nwọn si mu eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin bajẹ.

20. Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun wọn, Kiyesi, emi, ani emi, o ṣe idajọ lãrin ọwọ́-ẹran ti o sanra, ati eyiti o rù.

21. Nitoriti ẹnyin ti fi ẹgbẹ́ ati ejiká gbún, ti ẹ si ti fi iwo nyin kàn gbogbo awọn ti o li àrun titi ẹ fi tú wọn kakiri.

22. Nitorina ni emi o ṣe gbà ọwọ́-ẹran mi là, nwọn kì yio si jẹ ijẹ́ mọ, emi o si ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran.

23. Emi o si gbe oluṣọ́ agutan kan soke lori wọn, on o si bọ́ wọn, ani Dafidi iranṣẹ mi; on o bọ́ wọn, on o si jẹ oluṣọ́ agutan wọn.

Esek 34