Esek 33:10-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun ile Israeli; pe, Bayi li ẹnyin nwi, pe, Bi irekọja ati ẹ̀ṣẹ wa ba wà lori wa, ti awa si njoró ninu wọn, bawo li a o ti ṣe le wà lãye.

11. Sọ fun wọn pe, Bi emi ti wà, ni Oluwa Ọlọrun wi, emi kò ni inu-didun ni ikú enia buburu, ṣugbọn ki enia buburu yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀ ki o si yè: ẹ yipada, ẹ yipada kuro ninu ọ̀na buburu nyin; nitori kini ẹnyin o ṣe kú, Ile Israeli?

12. Nitorina, iwọ ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, ododo olododo kì yio gbà a là li ọjọ irekọja rẹ̀: bi o ṣe ti ìwa buburu enia buburu, on kì yio ti ipa rẹ̀ ṣubu li ọjọ ti o yipada kuro ninu ìwa buburu rẹ̀: bẹ̃ni olododo kì yio là nipa ododo rẹ̀ li ọjọ ti o dẹṣẹ.

13. Nigbati emi o wi fun olododo pe, yiyè ni yio yè, bi o ba gbẹkẹle ododo ara rẹ̀, ti o si ṣe aiṣedẽde, gbogbo ododo rẹ̀ li a kì yio ranti mọ, ṣugbọn nitori aiṣedẽde ti o ti ṣe, on o ti itori rẹ̀ kú.

14. Ẹ̀wẹ, nigbati emi wi fun enia buburu pe, Kikú ni iwọ o kú; bi on ba yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ti o si ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ;

15. Bi enia buburu ba mu ògo padà, ti o si san ohun ti o ti jí padà, ti o si nrin ni ilana ìye, li aiṣe aiṣedẽde; yiyè ni yio yè, on kì o kú.

16. A kì yio ṣe iranti gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ti ndá fun u: on ti ṣe eyi ti o tọ ti o si yẹ; on o yè nitõtọ.

17. Sibẹ awọn ọmọ enia rẹ wipe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba: ṣugbọn bi o ṣe ti wọn ni, ọ̀na wọn kò dọgba.

18. Nigbati olododo ba yipada kuro ninu ododo rẹ̀ ti o si ṣe aiṣedẽde, on o ti ipa rẹ̀ kú.

19. Ṣugbọn bi enia buburu bá yipada kuro ninu buburu rẹ̀, ti o si ṣe eyiti o tọ ti o si yẹ̀, on o ti ipa rẹ̀ wà lãye.

20. Sibẹ ẹnyin wi pe, Ọ̀na Oluwa kò dọgba, Ẹnyin ile Israeli, emi o dá olukuluku nyin li ẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀.

21. O si ṣe li ọdun ikejila ikolọ wa, li oṣu kẹwa, li ọjọ karun oṣu, ẹnikan ti o ti salà jade ni Jerusalemu tọ̀ mi wá, o wipe, A kọlù ilu na.

22. Ọwọ́ Oluwa si wà lara mi li àṣalẹ, ki ẹniti o salà na to de; o si ti ṣi ẹnu mi, titi on fi wá sọdọ mi li owurọ; ẹnu mi si ṣi, emi kò si yadi mọ.

23. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,

24. Ọmọ enia, awọn ti ngbe ahoro ile Israeli wọnni sọ, wipe, Abrahamu jẹ ẹnikan, on si jogun ilẹ na: ṣugbọn awa pọ̀, a fi ilẹ na fun wa ni ini.

25. Nitorina wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, ẹnyin njẹ ẹ̀jẹ mọ ẹran, ẹ si gbe oju nyin soke si awọn oriṣa nyin, ẹ si ta ẹjẹ silẹ, ẹnyin o ha ni ilẹ na?

26. Ẹnyin gbẹkẹle idà nyin, ẹ ṣe irira, olukuluku nyin bà obinrin aladugbò rẹ̀ jẹ́: ẹnyin o ha ni ilẹ na?

27. Iwọ wi bayi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Bi emi ti wà, nitõtọ, awọn ti o wà ninu ahoro na yio ti ipa idà ṣubu, ẹniti o si wà ni gbangba oko li emi o si fi fun ẹranko lati pajẹ, awọn ti o si wà ninu odi ati ninu ihò okuta yio ti ipa ajakalẹ-àrun kú.

Esek 33