1. O si ṣe li ọdun kejila, li oṣù kejila, li ọjọ ikini oṣù, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe,
2. Ọmọ enia, pohunrére fun Farao ọba Egipti, si wi fun u pe, Iwọ dabi ẹgbọ̀rọ kiniun awọn orilẹ-ède, iwọ si dabi dragoni ninu okun, iwọ si jade wá pẹlu awọn odò rẹ, iwọ ti fi ẹsẹ rẹ rú omi, o si ti bà awọn odò wọn jẹ́.
3. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitorina emi o nà àwọn mi sori rẹ pẹlu ẹgbẹ́ enia pupọ̀; nwọn o si fà ọ goke ninu àwọn mi.
4. Nigbana ni emi o fi ọ silẹ lori ilẹ, emi o gbe ọ sọ sinu igbẹ́, emi o mu ki gbogbo awọn ẹiyẹ oju ọrun ba le ọ lori, emi o si fi ọ bọ́ gbogbo awọn ẹranko aiye.
5. Emi o gbe ẹran ara rẹ kà awọn ori oke, gbogbo afonifoji li emi o fi giga rẹ kún.
6. Emi o si fi ẹ̀jẹ rẹ rin ilẹ nibiti iwọ nluwẹ́, ani si awọn oke; awọn odò yio si kún fun ọ.
7. Nigbati emi o ba mú ọ kuro, emi o bò ọrun, emi o si mu ki awọn ìrawọ inu rẹ̀ ṣokùnkun, emi o fi kũkũ bò õrùn, òṣupa kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn.
8. Gbogbo imọlẹ oju ọrun li emi o mu ṣokùnkun lori rẹ, emi o gbe okùnkun kà ilẹ rẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.
9. Emi o si bí ọ̀pọlọpọ enia ninu, nigbati emi o ba mu iparun rẹ wá sãrin awọn orilẹ-ède, si ilẹ ti iwọ kò ti mọ̀ ri.
10. Nitõtọ, emi o mu ki ẹnu yà ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède si ọ, awọn ọba wọn yio si bẹ̀ru gidigidi nitori rẹ, nigbati emi o ba mì idà mi niwaju wọn; nwọn o si warìri nigbagbogbo, olukuluku enia fun ẹmi ara rẹ̀, li ọjọ iṣubu rẹ.
11. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Idà ọba Babiloni yio wá sori rẹ.
12. Emi o mu ki ọ̀pọlọpọ enia rẹ ṣubu nipa idà awọn alagbara, ẹlẹ́rù awọn orilẹ-ẹ̀de ni gbogbo wọn; nwọn o si bà afẹ́ Egipti jẹ́, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ ni nwọn o parun.
13. Emi o si pa gbogbo awọn ẹranko inu rẹ̀ run kuro lẹba awọn omi nla, bẹ̃ni ẹsẹ enia kì yio rú wọn mọ́ lailai, tabi pátakò awọn ẹranko kì yio rú wọn.
14. Nigbana li emi o mu ki omi wọn ki o rẹlẹ, emi o si mu ki odò wọn ki o ṣàn bi oróro, li Oluwa Ọlọrun wi.
15. Nigbati emi o mu ki ilẹ Egipti di ahoro ti ilẹ na yio si di alaini ohun ti o kún inu rẹ̀ ri, nigbati emi o kọlù gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀, nigbana ni nwọn o mọ̀ pe emi li Oluwa.