Esek 31:16-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Emi mu awọn orilẹ̀-èdè mì nipa iró iṣubu rẹ̀, nigbati mo sọ ọ sinu ipòokú, pẹlu awọn ti o sọkalẹ sinu ihò, ati gbogbo igi Edeni, awọn àṣayan ati awọn ti o dara jù ti Lebanoni, gbogbo awọn ti o mu omi, li a o tù ninu ni ìsalẹ aiye.

17. Awọn pẹlu sọkalẹ lọ sinu ipò-okú pẹlu rẹ̀ sọdọ awọn ti a fi idà pa; awọn ti o si jẹ apá rẹ̀, ti ngbe abẹ òjiji rẹ̀ li ãrin awọn keferi.

18. Tani iwọ jọ li ogo ati ni titobi lãrin awọn igi Edeni? sibẹ a o mu ọ wá ilẹ pẹlu awọn igi Edeni si ìsalẹ aiye, iwọ o dubulẹ li ãrin awọn alaikọlà, pẹlu awọn ti a fi idà pa. Eyi ni Farao ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

Esek 31