Esek 3:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PẸLUPẸLU o wi fun mi pe, Ọmọ enia, jẹ ohun ti iwọ ri, jẹ iká-iwé yi, si lọ ba ile Israeli sọrọ.

2. Mo si ya ẹnu mi, o si mu mi jẹ iká-iwé na.

3. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, mu ki ikùn rẹ jẹ, ki o si fi iká-iwé yi ti emi fi fun ọ kún inu rẹ. Nigbana ni mo jẹ ẹ, o si dabi oyin li ẹnu ni didùn.

4. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, Lọ, tọ̀ ile Israeli lọ ki o si fi ọ̀rọ mi ba wọn sọrọ.

5. Nitori a kò ran ọ si enia ède ajeji ati sisọrọ, ṣugbọn si ile Israeli.

6. Ki iṣe si ọ̀pọlọpọ enia ède ajeji, ati ède sisọrọ, ọ̀rọ ẹniti iwọ kò le gbọ́. Nitotọ emi iba rán ọ si wọn, nwọn iba gbọ́ tirẹ.

Esek 3