Esek 27:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ọ̀gbọ daradara iṣẹ-ọnà lati Egipti wá li eyiti iwọ ta fi ṣe igbokun rẹ; aṣọ aláro ati purpili lati erekusu Eliṣa wá li eyiti a fi bò ọ.

8. Awọn ara ilu Sidoni ati Arfadi ni awọn ara ọkọ̀ rẹ̀: awọn ọlọgbọn rẹ, Iwọ Tire, ti o wà ninu rẹ, li awọn atọkọ̀ rẹ.

9. Awọn àgba Gebali, ati awọn ọlọgbọn ibẹ̀, wà ninu rẹ bi adikọ̀ rẹ: gbogbo ọkọ̀ òkun pẹlu awọn ara ọkọ̀ wọn wà ninu rẹ lati ma ṣòwo rẹ.

10. Awọn ti Persia, ati ti Ludi, ati ti Futi, wà ninu ogun rẹ, awọn ologun rẹ: nwọn fi apata ati ìbori-ogun kọ́ ninu rẹ; nwọn fi ẹwà rẹ hàn.

11. Awọn enia Arfadi, pẹlu awọn ogun rẹ, wà lori odi rẹ yika, ati awọn akọ-jamã wà ni ile-iṣọ rẹ: nwọn fi apata kọ́ sara odi rẹ yika; nwọn ti ṣe ẹwà rẹ pé.

12. Tarṣiṣi ni oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ̀ ọ̀rọ̀ rẹ; pẹlu fadakà, irin, tánganran, ati ojé, nwọn ti ṣòwo li ọja rẹ.

13. Jafani, Tubali, ati Meṣeki, awọn li awọn oniṣòwo rẹ: nwọn ti fi ẹrú ati ohun-elò idẹ ṣòwo li ọjà rẹ.

14. Awọn ti ile Togarma fi ẹṣin, ati ẹlẹṣin ati ibaka ṣòwo li ọjà rẹ.

15. Awọn enia Dedani li awọn oniṣòwo rẹ; ọ̀pọlọpọ erekuṣu ni mba ọ ṣòwo, nwọn mu ehin-erin ati igi eboni wá fun ọ lati rà.

16. Siria li oniṣòwo rẹ nitori ọ̀pọlọpọ iṣẹ ọwọ́ rẹ: nwọn ntà emeraldi li ọjà rẹ, pẹlu purpili, ati iṣẹ oniṣẹ-ọnà, ati ọ̀gbọ daradara, ati iyùn, ati agate.

Esek 27