23. Harani, ati Kanneh, ati Edeni, awọn oniṣòwo Ṣeba, Assuru, ati Kilmadi, ni awọn oniṣòwo rẹ.
24. Wọnyi li awọn oniṣòwo rẹ li onirũru nkan, ni aṣọ alaro, ati oniṣẹ-ọnà, ati apoti aṣọ oniyebiye, ti a fi okùn dì, ti a si fi igi kedari ṣe, ninu awọn oniṣòwo rẹ.
25. Awọn ọkọ Tarṣiṣi ni èro li ọjà rẹ: a ti mu ọ rẹ̀ si i, a si ti ṣe ọ logo li ãrin okun.
26. Awọn atukọ̀ rẹ ti mu ọ wá sinu omi nla: ẹfũfu ilà-õrun ti fọ́ ọ li ãrin okun.
27. Ọrọ̀ rẹ ati ọjà rẹ, ọjà tità rẹ, awọn atukọ̀ rẹ, ati atọ́kọ̀ rẹ, adikọ̀ rẹ, ati awọn alábarà rẹ, ati gbogbo awọn ologun rẹ, ti o wà ninu rẹ, ati ninu gbogbo ẹgbẹ́ rẹ, ti o wà li ãrin rẹ, yio ṣubu li ãrin okun li ọjọ iparun rẹ.