2. Ọmọ enia, doju kọ awọn ara Ammoni, si sọtẹlẹ si wọn;
3. Si wi fun awọn ara Ammoni pe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun: Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Nitori ti iwọ wipe, Aha, si ibi mimọ́ mi, nigbati o di àilọwọ, ati si ilẹ Israeli, nigbati o di ahoro; ati si ilẹ Juda, nigbati nwọn lọ ni ìgbekun;
4. Kiyesi i, nitorina emi o fi ọ le awọn enia ilà-õrùn lọwọ fun ini, nwọn o si gbe ãfin wọn kalẹ ninu rẹ, nwọn o si ṣe ibugbe wọn ninu rẹ: nwọn o jẹ eso rẹ, nwọn o si mu wàra rẹ.
5. Emi o si sọ Rabba di ibujẹ fun ibakasiẹ, ati awọn ọmọ Ammoni di ibùsun fun agbo-ẹran: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
6. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoriti iwọ ti pa atẹ́wọ, ti o si ti fi ẹsẹ kì ilẹ, ti o si yọ̀ li ọkàn pẹlu gbogbo aránkan rẹ si ilẹ Israeli:
7. Kiye si i, nitorina, emi o nà ọwọ́ mi le ọ, emi o si fi ọ fun awọn keferi fun ikogun; emi o si ke ọ kuro lãrin awọn enia, emi o si jẹ ki o ṣegbé kuro ninu ilẹ gbogbo: emi o pa ọ run; iwọ o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
8. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitoripe Moabu ati Seiri wipe, Kiye si i, ile Juda dabi gbogbo awọn keferi;
9. Nitorina, kiye si i, emi o ṣi ìha Moabu kuro lati awọn ilu gbogbo, kuro ninu awọn ilu rẹ̀ ti o wà li àgbegbe rẹ̀, ogo ilẹ na, Bet-jeṣimoti, Baalimeoni, ati Kiri-ataimu,
10. Fun awọn ọmọ ìla-orun, pẹlu awọn ara Ammoni, emi o si fi wọn fun ni ni iní; ki a má ba ranti awọn ara Ammoni lãrin orilẹ-ède mọ.