12. On ti fi eke dá ara rẹ̀ lagara, ifõfo nla rẹ̀ kò si jade kuro lara rẹ̀ ifõfo rẹ̀ yio wà ninu iná.
13. Ninu ẽri rẹ̀ ni iwà ifẹkufẹ wà: nitori mo ti wẹ̀ ọ, iwọ kò si mọ́, a kì yio si tun wẹ̀ ọ kuro ninu ẽri rẹ mọ, titi emi o fi jẹ ki irúnu mi ba le ọ lori.
14. Emi Oluwa li o ti sọ ọ, yio si ṣẹ, emi o si ṣe e: emi kì yio pada sẹhìn, bẹ̃ni emi kì yio dasi, bẹ̃ni emi kì yio ronupiwada; gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati gẹgẹ bi iṣe rẹ ni nwọn o da ọ lẹjọ, li Oluwa Ọlọrun wi.
15. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
16. Ọmọ enia, kiye si i, mo mu ifẹ oju rẹ kuro lọdọ rẹ, nipa lilù kan: ṣugbọn iwọ kò gbọdọ gbãwẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọkun, bẹ̃ni omije rẹ kò gbọdọ ṣan silẹ.