7. Bayi li o ṣe panṣaga rẹ̀ pẹlu wọn, pẹlu gbogbo awọn aṣàyan ọkunrin Assiria, ati pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ li afẹjù: o fi gbogbo oriṣa wọn ba ara rẹ̀ jẹ.
8. Bẹ̃ni kò fi panṣaga rẹ̀ ti o mu ti Egipti wá silẹ: nitori nigba ewe rẹ̀ ni nwọn ba a sùn, nwọn si rin ọmú ìgba wundia rẹ̀, nwọn si dà panṣaga wọn si i lara.
9. Nitorina ni mo ti fi le ọwọ́ awọn olufẹ rẹ̀, le ọwọ́ awọn ara Assiria, awọn ti o fẹ li afẹju.
10. Awọn wọnyi tu ìhoho rẹ̀ silẹ: nwọn mu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nwọn si fi idà pa a: o si di ẹni-olokiki lãrin awọn obinrin; nitori pe nwọn ti mu idajọ ṣẹ si i lara.
11. Nigbati Aholiba aburo ri eyi, o wà bàjẹ ju on lọ ni ìwa ifẹkufẹ rẹ̀, ati ni panṣaga rẹ̀ ju ẹ̀gbọn rẹ̀ lọ ni panṣaga rẹ̀.
12. O fẹ awọn ara Asiria aludugbo rẹ̀ li afẹju, awọn balogun ati awọn olori, ti a wọ̀ li aṣọ daradara, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin, gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wuni.
13. Nigbana ni mo ri pe a bà a jẹ, awọn mejeji gba ọ̀na kan.
14. Ati pe o mu ki panṣaga rẹ̀ bi si i: nitori igbati o ri awọn ọkunrin ti a ṣe li àworan sara ogiri, ere awọn ara Kaldea ti a fi ododó ṣe li àworan,
15. Ti a dì li àmure li ẹ̀gbẹ, ti nwọn ṣe aṣejù ni rirẹ lawani ori wọn, gbogbo wọn jẹ ajagun-kẹkẹ́ ti a ba ma wò, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Babiloni ti Kaldea, ilẹ ibi wọn:
16. Bi o si ti fi oju rẹ̀ ri wọn, o fẹ wọn li afẹjù, o si ran onṣẹ si wọn si Kaldea.
17. Awọn ara Babiloni si tọ̀ ọ wá lori akete ifẹ, nwọn si fi panṣaga wọn bà a jẹ, a si bà a jẹ pẹlu wọn, ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ wọn.