Esek 23:36-49 Yorùbá Bibeli (YCE)

36. Oluwa tun sọ fun mi pe; Ọmọ enia, iwọ o ha dá Ahola ati Aholiba lẹ́jọ? nitõtọ sọ irira wọn fun wọn;

37. Pe, nwọn ti ṣe panṣaga ẹ̀jẹ si mbẹ lọwọ wọn, ati nipasẹ oriṣa wọn ni nwọn ti ṣe panṣaga, nwọn si ti jẹ ki awọn ọmọ wọn, ti nwọn bi fun mi, kọja lãrin iná fun wọn, lati run wọn.

38. Eyi ni nwọn si ṣe si mi; nwọn ti bà ibi mimọ́ mi jẹ li ọjọ kanna, nwọn sọ ọjọ isimi mi di aìlọwọ.

39. Nitoripe igbati nwọn pa awọn ọmọ wọn fun oriṣa wọn, nigbana ni nwọn wá ni ijọ kanna si ibi mimọ́ mi, lati sọ ọ di àilọwọ; si kiye si i, bayi ni nwọn ṣe lãrin ile mi.

40. Ati pẹlupẹlu, ti pe ẹnyin ranṣẹ pè awọn ọkunrin lati okẽre wá, sọdọ awọn ti a ranṣẹ pè; si kiyesi i, nwọn de: fun ẹniti iwọ wẹ̀ ara rẹ, ti o si le tirõ, ti o si fi ohun ọṣọ́ ṣe ara rẹ li ọṣọ́.

41. Ti o si joko lori àkete daradara, a si tẹ́ tabili siwaju rẹ̀, lori eyi ti iwọ gbe turari mi ati ororó mi lé.

42. Ati ohùn ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn pa rọ́rọ wà lọdọ rẹ̀: ati pẹlu enia lasan li a mu awọn Sabeani lati aginjù wá, ti nwọn fi jufù si apá wọn, ati ade daradara si ori wọn.

43. Nigbana ni mo wi fun on ti o gbó ni panṣaga, Nwọn o ha bá a ṣe panṣaga nisisiyi, ati on pẹlu wọn?

44. Sibẹsibẹ wọn wọle tọ̀ ọ, bi nwọn ti iwọle tọ̀ obinrin ti nṣe panṣaga: bẹ̃ni nwọn wọle tọ̀ Ahola ati Aholiba, awọn onifẹkufẹ obinrin.

45. Ati awọn ọkunrin olododo, nwọn o ṣe idajọ wọn, bi a ti iṣe idajọ awọn àgbere obinrin, ati bi a ti iṣe idajọ awọn obinrin ti o ta ẹjẹ silẹ; nitoripe àgbere ni nwọn, ẹjẹ si wà lọwọ wọn.

46. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ẹgbẹ kan tọ̀ wọn wá, emi o si fi wọn fun wọn lati kó wọn lọ, ati lati bà wọn jẹ.

47. Ẹgbẹ na yio si sọ wọn li okuta, nwọn o si fi idà pa wọn; nwọn o pa awọn ọmọ wọn ọkunrin, ati awọn ọmọ wọn obinrin, nwọn o si fi iná kun ile wọn.

48. Bayi li emi o jẹ ki ìwa ifẹkufẹ mọ lãrin ilẹ na, ki a ba le kọ́ gbogbo obinrin, ki nwọn má bà ṣe bi ifẹkufẹ nyin.

49. Nwọn o si san ẹ̀san ìwa ifẹkufẹ nyin si ori nyin, ẹnyin o si rù ẹ̀ṣẹ oriṣa nyin; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.

Esek 23