3. Nwọn si ṣe panṣaga ni Egipti; nwọn ṣe panṣaga nigba ewe wọn: nibẹ ni a tẹ̀ ọmú wọn, nibẹ ni wọn si rin ọmú igbà wundia wọn.
4. Orukọ wọn si ni Ahola, ti iṣe ẹ̀gbọn, ati Aholiba aburo rẹ̀: ti emi si ni nwọn, nwọn si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin. Orukọ wọn ni eyi; Samaria ni Ahola, Jerusalemu si li Aholiba.
5. Ahola si ṣe panṣaga, nigbati o jẹ ti emi; o si fẹ awọn olufẹ rẹ̀ li afẹju, awọn ara Assiria aladugbo rẹ̀,
6. Ti a fi aṣọ alaro bò lara, awọn balogun ati awọn olori, gbogbo nwọn jẹ ọmọkunrin ti o wun ni, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin.
7. Bayi li o ṣe panṣaga rẹ̀ pẹlu wọn, pẹlu gbogbo awọn aṣàyan ọkunrin Assiria, ati pẹlu gbogbo awọn ti o fẹ li afẹjù: o fi gbogbo oriṣa wọn ba ara rẹ̀ jẹ.
8. Bẹ̃ni kò fi panṣaga rẹ̀ ti o mu ti Egipti wá silẹ: nitori nigba ewe rẹ̀ ni nwọn ba a sùn, nwọn si rin ọmú ìgba wundia rẹ̀, nwọn si dà panṣaga wọn si i lara.
9. Nitorina ni mo ti fi le ọwọ́ awọn olufẹ rẹ̀, le ọwọ́ awọn ara Assiria, awọn ti o fẹ li afẹju.
10. Awọn wọnyi tu ìhoho rẹ̀ silẹ: nwọn mu awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nwọn si fi idà pa a: o si di ẹni-olokiki lãrin awọn obinrin; nitori pe nwọn ti mu idajọ ṣẹ si i lara.
11. Nigbati Aholiba aburo ri eyi, o wà bàjẹ ju on lọ ni ìwa ifẹkufẹ rẹ̀, ati ni panṣaga rẹ̀ ju ẹ̀gbọn rẹ̀ lọ ni panṣaga rẹ̀.
12. O fẹ awọn ara Asiria aludugbo rẹ̀ li afẹju, awọn balogun ati awọn olori, ti a wọ̀ li aṣọ daradara, awọn ẹlẹṣin ti o ngùn ẹṣin, gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wuni.
13. Nigbana ni mo ri pe a bà a jẹ, awọn mejeji gba ọ̀na kan.
14. Ati pe o mu ki panṣaga rẹ̀ bi si i: nitori igbati o ri awọn ọkunrin ti a ṣe li àworan sara ogiri, ere awọn ara Kaldea ti a fi ododó ṣe li àworan,
15. Ti a dì li àmure li ẹ̀gbẹ, ti nwọn ṣe aṣejù ni rirẹ lawani ori wọn, gbogbo wọn jẹ ajagun-kẹkẹ́ ti a ba ma wò, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Babiloni ti Kaldea, ilẹ ibi wọn:
16. Bi o si ti fi oju rẹ̀ ri wọn, o fẹ wọn li afẹjù, o si ran onṣẹ si wọn si Kaldea.
17. Awọn ara Babiloni si tọ̀ ọ wá lori akete ifẹ, nwọn si fi panṣaga wọn bà a jẹ, a si bà a jẹ pẹlu wọn, ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ wọn.
18. Bayi li o tú idi panṣaga rẹ̀ silẹ, o si tú ihòho rẹ̀ silẹ: nigbana li ọkàn mi ṣi kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn mi ti ṣi kuro lọdọ ẹ̀gbọn rẹ̀.
19. Sibẹsibẹ o mu panṣaga rẹ̀ bi si i ni pipè ọjọ ewe rẹ̀ si iranti, ninu eyi ti o ti ṣe panṣaga ni ilẹ Egipti.
20. Nitoripe o fẹ awọn olufẹ wọn li afẹju, ẹran-ara awọn ti o dabi ẹran-ara kẹtẹkẹtẹ, ati irú awọn ẹni ti o dabi irú ẹṣin.
21. Bayi ni iwọ pe ìwa ifẹkufẹ ìgba ewe rẹ wá si iranti, niti ririn ori ọmú rẹ lati ọwọ́ awọn ara Egipti, fun ọmú ìgba ewe rẹ.
22. Nitorina, iwọ Aholiba, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi o gbe awọn olufẹ rẹ dide si ọ, lọdọ awọn ti ọkàn rẹ ti ṣi, emi o si mu wọn doju kọ ọ niha gbogbo.