13. Nigbana ni mo ri pe a bà a jẹ, awọn mejeji gba ọ̀na kan.
14. Ati pe o mu ki panṣaga rẹ̀ bi si i: nitori igbati o ri awọn ọkunrin ti a ṣe li àworan sara ogiri, ere awọn ara Kaldea ti a fi ododó ṣe li àworan,
15. Ti a dì li àmure li ẹ̀gbẹ, ti nwọn ṣe aṣejù ni rirẹ lawani ori wọn, gbogbo wọn jẹ ajagun-kẹkẹ́ ti a ba ma wò, gẹgẹ bi iṣe awọn ara Babiloni ti Kaldea, ilẹ ibi wọn:
16. Bi o si ti fi oju rẹ̀ ri wọn, o fẹ wọn li afẹjù, o si ran onṣẹ si wọn si Kaldea.
17. Awọn ara Babiloni si tọ̀ ọ wá lori akete ifẹ, nwọn si fi panṣaga wọn bà a jẹ, a si bà a jẹ pẹlu wọn, ọkàn rẹ̀ si ṣi kuro lọdọ wọn.
18. Bayi li o tú idi panṣaga rẹ̀ silẹ, o si tú ihòho rẹ̀ silẹ: nigbana li ọkàn mi ṣi kuro lọdọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn mi ti ṣi kuro lọdọ ẹ̀gbọn rẹ̀.
19. Sibẹsibẹ o mu panṣaga rẹ̀ bi si i ni pipè ọjọ ewe rẹ̀ si iranti, ninu eyi ti o ti ṣe panṣaga ni ilẹ Egipti.
20. Nitoripe o fẹ awọn olufẹ wọn li afẹju, ẹran-ara awọn ti o dabi ẹran-ara kẹtẹkẹtẹ, ati irú awọn ẹni ti o dabi irú ẹṣin.
21. Bayi ni iwọ pe ìwa ifẹkufẹ ìgba ewe rẹ wá si iranti, niti ririn ori ọmú rẹ lati ọwọ́ awọn ara Egipti, fun ọmú ìgba ewe rẹ.
22. Nitorina, iwọ Aholiba, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiye si i, emi o gbe awọn olufẹ rẹ dide si ọ, lọdọ awọn ti ọkàn rẹ ti ṣi, emi o si mu wọn doju kọ ọ niha gbogbo.
23. Awọn ara Babiloni, ati gbogbo awọn ara Kaldea, Pekodu, ati Ṣoa, ati Koa, ati gbogbo awọn ara Assiria pẹlu wọn: gbogbo wọn jẹ ọmọkunrin ti o wunni, balogun ati awọn olori, awọn ọkunrin ti o li okiki, gbogbo wọn li o ngun ẹṣin.