1. Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,
2. Njẹ, iwọ ọmọ enia, iwọ o ha ṣe idajọ, iwọ o ha ṣe idajọ ilu ẹlẹjẹ na? nitõtọ, iwọ o jẹ ki o mọ̀ ohun irira rẹ̀ gbogbo.
3. Nitorina, iwọ wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Ilu ti o ta ẹjẹ silẹ lãrin rẹ̀, ki akoko rẹ̀ ki o le de, o si ṣe oriṣa si ara rẹ̀ lati sọ ara rẹ̀ di aimọ́.
4. Iwọ ti di ẹlẹbi niti ẹjẹ rẹ ti iwọ ti ta silẹ; iwọ si ti sọ ara rẹ di aimọ́ niti òriṣa rẹ ti iwọ ti ṣe, iwọ si ti mu ọjọ rẹ summọ tosí, iwọ si ti dé ọdun rẹ: nitorina ni mo ṣe sọ ọ di ẹgàn si awọn keferi, ati ẹsín si gbogbo ilẹ.
5. Awọn ti o sunmọ tosí, ati awọn ti o jìna si ọ, yio fi ọ ṣẹ̀sin, iwọ ti a bà orukọ rẹ̀ jẹ, ti a si bà ninu jẹ pupọ.