2. Ọmọ enia, kọju rẹ sihà Jerusalemu, si sọ ọ̀rọ si ibi mimọ́ wọnni, si sọtẹlẹ si ilẹ Israeli.
3. Si wi fun ilẹ Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ ọ, emi o si fa idà mi yọ kuro li akọ̀ rẹ̀, emi o si ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ.
4. Njẹ bi o ti ṣe pe emi o ke olododo ati enia buburu kuro lãrin rẹ, nitorina ni idà mi o ṣe jade lọ lati inu àkọ rẹ̀, si gbogbo ẹran-ara, lati gusù de ariwa:
5. Ki gbogbo ẹran-ara le mọ̀ pe emi Oluwa ti fà idà mi yọ kuro li àkọ rẹ̀: kì yio pada mọ lai.
6. Nitorina kerora, iwọ ọmọ enia, pẹlu ṣiṣẹ́ ẹgbẹ́ rẹ, ati pẹlu ikerora kikoro niwaju wọn.
7. Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi nkerora? iwọ o dahùn wipe, Nitori ihìn na; nitoripe o de: olukuluku ọkàn ni yio yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yio si ṣe ailokun, olukuluku ẹmi yio si dakú, gbogbo ẽkún ni yio ṣe ailagbara bi omi: kiyesi i, o de, a o si mu u ṣẹ, ni Oluwa Ọlọrun wi.
8. Ọ̀rọ Oluwa si tun tọ̀ mi wá, wipe,
9. Ọmọ enia, sọtẹlẹ, si wipe, Bayi li Oluwa wi; Wipe, Idà, idà ti a pọ́n, ti a si dán pẹlu:
10. A pọ́n ọ lati pa enia pupọ; a dán a lati ma kọ màna: awa o ha ma ṣe ariyá? ọgọ ọmọ mi, o gàn gbogbo igi.
11. On si ti fi i le ni lọwọ lati dán, ki a ba le lò o; idà yi li a pọ́n, ti a si dán, lati fi i le ọwọ́ apani.
12. Kigbe, ki o si wu, ọmọ enia: nitori yio wá sori awọn enia mi, yio wá sori gbogbo ọmọ-alade Israeli: ìbẹru nla yio wá sori awọn enia mi nitori idà na: nitorina lu itan rẹ.