26. Emi si bà wọn jẹ́ ninu ẹ̀bun ara wọn, nitipe nwọn mu gbogbo awọn akọbi kọja lãrin iná, ki emi ba le sọ wọn di ahoro, ki nwọn le bà mọ̀ pe emi ni Oluwa.
27. Nitorina, ọmọ enia, sọ fun ile Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ninu eyi pẹlu baba nyin ti sọ̀rọ odi si mi, nitipe nwọn ti dẹṣẹ si mi.
28. Nitori nigbati mo ti mu wọn de ilẹ, niti eyiti mo gbé ọwọ́ mi soke lati fi i fun wọn, nigbana ni nwọn ri olukuluku oke giga, ati gbogbo igi bibò, nwọn si ru ẹbọ wọn nibẹ, nwọn si gbe imunibinu ọrẹ wọn kalẹ nibẹ: nibẹ pẹlu ni nwọn ṣe õrun didùn wọn, nwọn si ta ohun-ọrẹ mimu silẹ nibẹ.
29. Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Kini ibi giga ti ẹnyin nlọ na? Orukọ rẹ̀ ni a si npe ni Bama titi o fi di oni oloni.