Esek 18:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Kiye si i, gbogbo ọkàn ni t'emi; gẹgẹ bi ọkàn baba ti jẹ t'emi, bẹ̃ni t'emi ni ọkàn ọmọ pẹlu; ọkàn ti o bá ṣẹ̀, on o kú.

5. Ṣugbọn bi enia kan ba ṣe olõtọ, ti o si ṣe eyiti o tọ ati eyiti o yẹ,

6. Ti kò si jẹun lori oke, ti kò si gbe oju rẹ̀ soke si awọn oriṣa ile Israeli, ti kò si bà obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, ti kò sì sunmọ obinrin ti o wà ninu aimọ́ rẹ̀.

7. Ti kò si ni ẹnikan lara, ṣugbọn ti o ti fi ohun ògo onigbèse fun u, ti kò fi agbara kó ẹnikẹni, ti o ti fi onjẹ rẹ̀ fun ẹniti ebi npa, ti o si ti fi ẹwu bo ẹni-ihoho.

8. Ẹniti kò fi fun ni lati gba ẹdá, bẹ̃ni kò gba elékele, ti o ti fa ọwọ́ rẹ̀ kuro ninu aiṣedẽde, ti o ti mu idajọ otitọ ṣẹ lãrin ọkunrin ati ọkunrin,

9. Ti o ti rìn ninu aṣẹ mi, ti o si ti pa idajọ mi mọ, lati hùwa titọ́; on ṣe olõtọ, yiyè ni yio yè, ni Oluwa Ọlọrun wi.

10. Bi o ba bi ọmọkunrin kan ti iṣe ọlọṣà, oluta ẹ̀jẹ silẹ, ti o si nṣe ohun ti o jọ ọkan ninu nkan wọnyi si arakunrin rẹ̀.

11. Ti kò si ṣe ọkan ninu gbogbo iṣẹ wọnni, ṣugbọn ti o tilẹ ti jẹun lori oke, ti o si ba obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ,

12. Ti o ti ni talaka ati alaini lara; ti o ti fi agbara koni, ti kò mu ohun ògo pada, ti o ti gbe oju rẹ̀ soke si oriṣa, ti o ti ṣe ohun irira,

Esek 18