1. Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,
2. Kini ẹnyin rò ti ẹnyin fi npowe yi niti ilẹ Israeli, pe, Awọn baba ti jẹ eso àjara kíkan, ehin awọn ọmọ si kan.
3. Oluwa Ọlọrun wipe, bi mo ti wà, ẹnyin kì yio ri àye lati powe yi mọ ni ilẹ Israeli.
4. Kiye si i, gbogbo ọkàn ni t'emi; gẹgẹ bi ọkàn baba ti jẹ t'emi, bẹ̃ni t'emi ni ọkàn ọmọ pẹlu; ọkàn ti o bá ṣẹ̀, on o kú.
5. Ṣugbọn bi enia kan ba ṣe olõtọ, ti o si ṣe eyiti o tọ ati eyiti o yẹ,
6. Ti kò si jẹun lori oke, ti kò si gbe oju rẹ̀ soke si awọn oriṣa ile Israeli, ti kò si bà obinrin aladugbo rẹ̀ jẹ, ti kò sì sunmọ obinrin ti o wà ninu aimọ́ rẹ̀.