20. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, mo dojukọ awọn tìmtim nyin, ti ẹnyin fi nṣọdẹ ọkàn nibẹ lati mu wọn fò, emi o si yà wọn kuro li apá nyin, emi o si jẹ ki awọn ọkàn na lọ, ani awọn ọkàn ti ẹnyin ndọdẹ lati mu fò.
21. Gèle nyin pẹlu li emi o ya, emi o si gba awọn enia mi lọwọ nyin, nwọn kì yio si si lọwọ nyin mọ lati ma dọdẹ wọn; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.
22. Nitoripe eke li ẹnyin fi mu ọkàn awọn olododo kãnu, awọn ẹniti emi kò mu kãnu, ẹnyin si mu ọwọ́ enia buburu le, ki o má ba pada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀ nipa ṣiṣe ileri ìye fun u:
23. Nitorina ẹnyin kì yio ri asan mọ, ẹ kì yio si ma fọ àfọṣẹ, nitoriti emi o gba awọn enia mi kuro li ọwọ́ nyin, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa.