10. Nitori, ani nitori ti nwọn ti tàn awọn enia mi wipe, Alafia; bẹ̃ni kò si alafia, ọkan si mọ ogiri, si kiyesi, awọn miran si nfi amọ̀ ti a kò pò rẹ́ ẹ.
11. Wi fun awọn ti nfi amọ̀ aipò rẹ́ ẹ, pe, yio ṣubu; òjo yio rọ̀ pupọ; ati Ẹnyin, yinyín nla, o si bọ́; ẹfũfu lile yio si ya a.
12. Kiyesi i, nigbati ogiri na ba wo, a kì yio ha wi fun nyin pe, Rirẹ́ ti ẹnyin rẹ́ ẹ ha dà?
13. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o tilẹ fi ẹfũfu lile ya a ni irúnu mi; òjo yio si rọ̀ pupọ ni ibinu mi, ati yinyin nla ni irúnu mi lati run u.
14. Bẹ̃ni emi o wo ogiri ti ẹnyin fi amọ̀ aipò rẹ́ lulẹ, emi o si mu u wá ilẹ, tobẹ̃ ti ipilẹ rẹ̀ yio hàn, yio si ṣubu, a o si run nyin li ãrin rẹ̀: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.
15. Bayi li emi o mu ibinu mi ṣẹ lori ogiri na, ati lori awọn ti o fi amọ̀ aipò rẹ ẹ, emi o si wi fun nyin pe, Ogiri na kò si mọ ati awọn ti o ti rẹ́ ẹ;
16. Eyini ni, awọn woli Israeli, ti nwọn sọtẹlẹ niti Jerusalemu, ti nwọn si ri iran alafia fun u, bẹ̃ni alafia kò si, ni Oluwa Ọlọrun wi.
17. Iwọ ọmọ enia, dojukọ awọn ọmọbinrin awọn enia rẹ bẹ̃ gẹgẹ, ti nwọn nsọtẹlẹ lati ọkàn ara wọn wá; ki o si sọtẹlẹ si wọn.