Esek 10:12-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ati gbogbo ara wọn, ati ẹhìn wọn, ati ọwọ́ wọn ati iyẹ́ wọn, ati awọn kẹkẹ́, kún fun oju yika kiri kẹkẹ́, ti awọn mẹrẹrin ni.

13. Niti awọn kẹkẹ́, a ke si wọn li etí mi wipe, Kẹkẹ́!

14. Olukuluku wọn si ni oju mẹrin, oju ekini oju kerubu, oju keji, oju enia, ati ẹkẹta oju kiniun, ati ẹkẹrin oju idi.

15. A si gbe awọn kerubu soke, eyi ni ẹda alãye ti mo ri lẹba odò Kebari.

16. Nigbati awọn kerubu si lọ, awọn kẹkẹ lọ li ẹgbẹ́ wọn: nigbati awọn kerubu si gbe iyẹ́ wọn soke lati fò soke kuro lori ilẹ, kẹkẹ́ kanna kò yipada kuro li ẹgbẹ́ wọn.

17. Nigbati nwọn duro, wọnyi duro; nigbati a si gbe wọn soke, wọnyi gbe ara wọn soke pẹlu; nitori ẹmi ẹda alãye na mbẹ ninu wọn.

Esek 10