Esek 1:5-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Pẹlupẹlu lati ãrin rẹ̀ wá, aworan ẹda alãye mẹrin, eyi si ni irí wọn, nwọn ni aworan enia.

6. Olukuluku si ni oju mẹrin, olukuluku si ni iyẹ mẹrin.

7. Ẹsẹ wọn si tọ́, atẹlẹsẹ wọn si dabi atẹlẹsẹ ọmọ malũ: nwọn si tàn bi awọ̀ idẹ didan.

8. Nwọn si ni ọwọ́ enia labẹ iyẹ́ wọn, li ẹgbẹ wọn mẹrẹrin, awọn mẹrẹrin si ni oju wọn ati iyẹ́ wọn.

9. Iyẹ́ wọn si kàn ara wọn; nwọn kò yipada nigbati nwọn lọ, olukuluku wọn lọ li ọkankan ganran.

10. Niti aworan oju wọn, awọn mẹrẹrin ni oju enia, ati oju kiniun, niha ọtun: awọn mẹrẹrin si ni oju malu niha osì; awọn mẹrẹrin si ni oju idì.

Esek 1