Eks 9:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Wọle tọ̀ Farao lọ ki o si wi fun u pe, Bayi li OLUWA, Ọlọrun awọn Heberu wi, Jẹ ki awọn enia mi ki o lọ, ki nwọn le sìn mi.

2. Nitoripe, bi iwọ ba kọ̀ lati jẹ ki nwọn lọ, ti iwọ si da wọn duro sibẹ̀,

3. Kiyesi i, ọwọ́ OLUWA mbẹ lara ẹran-ọ̀sin rẹ ti mbẹ li oko, lara ẹṣin, lara kẹtẹkẹtẹ, lara ibakasiẹ, lara ọwọ́-malu, ati lara agbo-agutan wọnni: ajakalẹ-àrun buburu mbọ̀.

4. OLUWA yio si pàla si agbedemeji ẹran-ọ̀sin Israeli ati ẹran-ọ̀sin Egipti: kò si ohun kan ti yio kú ninu gbogbo eyiti iṣe ti awọn ọmọ Israeli.

5. OLUWA si dá akokò kan wipe, Li ọla li OLUWA yio ṣe nkan yi ni ilẹ yi.

6. OLUWA si ṣe nkan na ni ijọ́ keji, gbogbo ẹran-ọ̀sin Egipti si kú: ṣugbọn ninu ẹran-ọ̀sin awọn ọmọ Israeli ọkanṣoṣọ kò si kú.

Eks 9