Eks 7:8-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,

9. Nigbati Farao yio ba wi fun nyin pe, Ẹ fi iṣẹ-iyanu kan hàn: nigbana ni ki iwọ ki o wi fun Aaroni pe, Mú ọpá rẹ, ki o si fi i lelẹ niwaju Farao, yio si di ejò.

10. Mose ati Aaroni si wọle tọ̀ Farao lọ, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn: Aaroni si fi ọpá rẹ̀ lelẹ niwaju Farao ati niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀, o si di ejò.

11. Nigbana ni Farao pẹlu pè awọn ọlọgbọ́n ati awọn oṣó: awọn pẹlu, ani awọn alalupayida Egipti, si fi idán wọn ṣe bẹ̃ gẹgẹ.

12. Nitoriti olukuluku nwọn fi ọpá rẹ̀ lelẹ, nwọn si di ejò: ṣugbọn ọpá Aaroni gbe ọpá wọn mì.

13. Aiya Farao si le, kò si fetisi ti wọn; bi OLUWA ti wi.

14. OLUWA si wi fun Mose pe, Aiya Farao di lile, o kọ̀ lati jẹ ki awọn enia na ki o lọ.

15. Tọ̀ Farao lọ li owurọ̀; kiyesi i, o njade lọ si odò; ki iwọ ki o si duro lati pade rẹ̀ leti odò; ati ọpá nì ti o di ejò ni ki iwọ ki o mú li ọwọ́ rẹ.

Eks 7